Ti wahala ba wa? Akiyesi! ÒGUN PÀJÁWÌRÌ TÍ Ó Ń DÈNÀ OYÚN NÍNÍ · 12/8/2017  · OYÚN...

2
PHARMACY ÒGUN PÀJÁWÌRÌ TÍ Ó Ń DÈNÀ OYÚN NÍNÍ Akiyesi! Ti o ko ba ri nkan oṣu re laarin ọjọ meje ti o ti n reti rẹ, lọ ri awọn eleto ilera rẹ kiakia fun ayẹwo ati itọni. O ṣe ṣe ki o ti loyun. Alaye kikun! w Ẹ ma ṣe lo ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní ju ẹkan lọ laarin wakati mẹrin-le-logun, awọn ilana ifetosọmọbibi miran wa ti o munadoko w Maṣe bẹru tabi foya. Ti o ba n ni ibalopo leralera, lilo ilana ifetosọmọbibi (ogun onikoro, alabẹrẹ, oloju-ara ati onisana apa) jẹ ọna ti o munadoko lati dena oyun w Ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní kii dabobo lọwọ arun ibalopo bii Eedi. Ti wahala ba wa? Ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní kii fa inira ti o le. Nigba miran, o le fa inira pẹpẹpẹ bii ki eebi ma gbe ni ati ori fifọ. O si le fa ki nkan oṣu awọn obirin kọọkan ma ṣe segesege, ṣugbon gbogbo eyi ki i ṣe okunfa aisan si ni lara lọjọ iwaju bẹ si ni kii fa airọmọbi. O dara lati lo ogun yi ni kete lẹyin ibalopo lai lo idabobo kankan. Modern Family Planning Methods: Safe and Trusted Dena oyun nini lẹyin ti o ba ni ibalọpọ lai lo idabobo kankan Nibo ni a ti le ri Ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní? Ẹ le gba ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní ni ile iwosan ijọba ati aladani (ile ita ogun) Ẹ le gba ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní lai si iwe igba ogun.

Transcript of Ti wahala ba wa? Akiyesi! ÒGUN PÀJÁWÌRÌ TÍ Ó Ń DÈNÀ OYÚN NÍNÍ · 12/8/2017  · OYÚN...

Page 1: Ti wahala ba wa? Akiyesi! ÒGUN PÀJÁWÌRÌ TÍ Ó Ń DÈNÀ OYÚN NÍNÍ · 12/8/2017  · OYÚN NÍNÍ Akiyesi! Ti o ko ba ri nkan oṣu re laarin ọjọ meje ti o ti n reti rẹ,

PHARMACY

ÒGUN PÀJÁWÌRÌ TÍ Ó Ń DÈNÀ OYÚN NÍNÍ

Akiyesi! Ti o ko ba ri nkan oṣu re laarin ọjọ meje ti o ti n reti rẹ,

lọ ri awọn eleto ilera rẹ kiakia fun ayẹwo ati itọni. O ṣe

ṣe ki o ti loyun.

Alaye kikun!

w Ẹ ma ṣe lo ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní ju

ẹkan lọ laarin wakati mẹrin-le-logun, awọn ilana

ifetosọmọbibi miran wa ti o munadoko

w Maṣe bẹru tabi foya. Ti o ba n ni ibalopo leralera,

lilo ilana ifetosọmọbibi (ogun onikoro, alabẹrẹ,

oloju-ara ati onisana apa) jẹ ọna ti o munadoko lati

dena oyun

w Ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní kii dabobo lọwọ

arun ibalopo bii Eedi.

Ti wahala ba wa?Ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní kii fa inira ti o le. Nigba miran, o le fa inira pẹpẹpẹ bii ki eebi ma gbe ni ati ori fifọ. O si le fa ki nkan oṣu awọn obirin kọọkan ma ṣe segesege, ṣugbon gbogbo eyi ki i ṣe okunfa aisan si ni lara lọjọ iwaju bẹ si ni kii fa airọmọbi.

O dara lati lo ogun yi ni kete lẹyin ibalopo

lai lo idabobo kankan.

Modern Family Planning Methods: Safe and Trusted

Dena oyun nini lẹyin ti o ba ni ibalọpọ lai lo idabobo kankan

Nibo ni a ti le ri Ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní?Ẹ le gba ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní ni ile iwosan ijọba ati aladani (ile ita ogun)

Ẹ le gba ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní lai si iwe igba ogun.

Page 2: Ti wahala ba wa? Akiyesi! ÒGUN PÀJÁWÌRÌ TÍ Ó Ń DÈNÀ OYÚN NÍNÍ · 12/8/2017  · OYÚN NÍNÍ Akiyesi! Ti o ko ba ri nkan oṣu re laarin ọjọ meje ti o ti n reti rẹ,

Lo ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní bi o ti yẹ:

l Nigbati ilana idabobo ti a lo ba ja ni kulẹ tabi ti a ko lo bi o ṣe yẹ. Fun apẹrẹ, ti rọba idabobo ba bẹ tabi ti a ba gbagbe lati lo ogun onikoro lojojumọ

l Nigbati a ba fi ipa ba ni ni ibalopo

l Nigbati a ko ba lo ilana idabobo kankan

Nigbawo ati bawo ni a se n lo?Ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní yíó ṣiṣe to munadoko níwọn igba ti a ba tete lo lẹyin ibalopo lai lo idabobo kankan. Sugbọn ogun yi o ni ṣiṣe ti a ba lo lẹyin ọjọ marun ti a ni ibalopo lai lo idabobo kankan.

Kíni ògùn yi?Ògun pàjáwìrì yi ń dènà oyún níní laarin ọgọfa wakati (ọjọ marun) lẹyin ibalopo lai lo idabobo kankan.

Gbogbo obirin ti o ti to bimo ni o le lo ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní lẹyin ìbálòpo lai lo ìdábòbò kankan.

Bawo lo ṣe n ṣiṣe?Ògun pàjáwìrì yi ma ń dènà oyún níní. Ko le ṣe ifarapa fun oyun ti o ti wa lara, bẹ si ni ki i nṣe oyun. Ko le ṣe idabobo fun ibalopo ti a ni lẹhin ti a ba ti lo ogun yii.

Ẹ ma ṣe lo ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní ju ẹkan lọ laarin wakati mẹrin-le-logun.

Pẹlu iranlọwọ akọṣẹmọṣẹ ifetosọmọbibi, ẹ le yan ilana miran ti o fi ni lọkan balẹ ju ilana pajawiri lọ, fun apẹrẹ ogun onikoro, alabẹrẹ, oloju-ara, oniṣana apa ati bẹbẹlo.

Ti o ba nṣe iyemeji, lọ ri eleto ilera re

Ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní ki ṣe oun ti a le fi rọpo ilana ifetosọmọbibi.